-
2 Àwọn Ọba 23:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Lẹ́yìn náà, ó kó gbogbo àwọn àlùfáà jáde kúrò ní àwọn ìlú Júdà, ó sì sọ àwọn ibi gíga tí àwọn àlùfáà ti ń mú ẹbọ rú èéfín di ibi tí kò ṣeé lò fún ìjọsìn, láti Gébà+ títí dé Bíá-ṣébà.+ Ó tún wó àwọn ibi gíga ẹnubodè tó wà ní ibi àtiwọ ẹnubodè Jóṣúà olórí ìlú náà, èyí tó wà lápá òsì tí èèyàn bá wọ ẹnubodè ìlú náà. 9 Àwọn àlùfáà ibi gíga kò ṣiṣẹ́ níbi pẹpẹ Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù,+ àmọ́ wọ́n máa ń jẹ búrẹ́dì aláìwú pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn.
-
-
Nehemáyà 9:34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 Ní ti àwọn ọba wa, àwọn ìjòyè wa, àwọn àlùfáà wa àti àwọn baba ńlá wa, wọn ò pa Òfin rẹ mọ́, wọn ò sì fiyè sí àwọn àṣẹ rẹ tàbí àwọn ìránnilétí* rẹ tí o fi kìlọ̀ fún wọn.
-