ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 32:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 32 Wò ó! Ọba+ kan máa jẹ fún òdodo,+

      Àwọn ìjòyè sì máa ṣàkóso fún ìdájọ́ òdodo.

  • Àìsáyà 60:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Dípò bàbà, màá mú wúrà wá,

      Dípò irin, màá mú fàdákà wá

      Dípò igi, bàbà

      Àti dípò òkúta, irin;

      Màá fi àlàáfíà ṣe àwọn alábòójútó rẹ,

      Màá sì fi òdodo ṣe àwọn tó ń yan iṣẹ́ fún ọ.+

  • Jeremáyà 22:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 ‘Àmọ́ ojú rẹ àti ọkàn rẹ ò kúrò lórí bí o ṣe máa jẹ èrè tí kò tọ́,

      Lórí bí o ṣe máa ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀

      Àti lórí bí o ṣe máa lu jìbìtì àti bí o ṣe máa lọ́ni lọ́wọ́ gbà.’

  • Jeremáyà 23:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 “Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “tí màá gbé èéhù* kan tó jẹ́ olódodo dìde fún Dáfídì.+ Ọba kan máa jẹ,+ á sì fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà, á dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, á sì ṣe òdodo ní ilẹ̀ náà.+

  • Ìsíkíẹ́lì 22:27
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 27 Àwọn olórí tó wà láàárín rẹ̀ dà bí ìkookò tó ń fa ẹran ya; wọ́n ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì ń pa àwọn èèyàn* láti jẹ èrè tí kò tọ́.+

  • Ìsíkíẹ́lì 46:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Ìjòyè náà kò gbọ́dọ̀ fipá gba ohun ìní kankan tó jẹ́ ogún àwọn èèyàn náà. Inú nǹkan ìní tirẹ̀ ni kó ti fún àwọn ọmọ rẹ̀ ní ogún, kí wọ́n má bàa lé ìkankan nínú àwọn èèyàn mi kúrò nídìí ohun ìní wọn.’”

  • Míkà 3:1-3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Mo sọ pé: “Ẹ jọ̀ọ́ ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí ilé Jékọ́bù

      Àti ẹ̀yin aláṣẹ ilé Ísírẹ́lì.+

      Ṣé kò yẹ kí ẹ mọ ohun tó tọ́?

       2 Àmọ́ ẹ kórìíra ohun rere,+ ẹ sì fẹ́ràn ohun búburú;+

      Ẹ bó àwọn èèyàn mi láwọ, ẹ sì ṣí ẹran kúrò lára egungun wọn.+

       3 Ẹ tún jẹ ẹran ara àwọn èèyàn mi,+

      Ẹ sì bó wọn láwọ,

      Ẹ fọ́ egungun wọn, ẹ sì rún un sí wẹ́wẹ́,+

      Bí ohun tí wọ́n sè nínú ìkòkò,* bí ẹran nínú ìkòkò oúnjẹ.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́