-
Àìsáyà 11:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà tún máa na ọwọ́ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì, láti gba àṣẹ́kù àwọn èèyàn rẹ̀ pa dà, àwọn tó ṣẹ́ kù láti Ásíríà,+ Íjíbítì,+ Pátírọ́sì,+ Kúṣì,+ Élámù,+ Ṣínárì,* Hámátì àti àwọn erékùṣù òkun.+ 12 Ó máa gbé àmì* kan sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè, ó sì máa kó àwọn tó fọ́n ká lára Ísírẹ́lì jọ,+ ó máa kó àwọn tó tú ká lára Júdà jọ láti ìkángun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé.+
-
-
Jeremáyà 30:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 “Ní tìrẹ, ìwọ Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi, má fòyà,” ni Jèhófà wí,
“Má sì jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, ìwọ Ísírẹ́lì.+
Nítorí màá gbà ọ́ láti ibi tó jìnnà réré
Àti àwọn ọmọ rẹ láti oko ẹrú tí wọ́n wà.+
Jékọ́bù á pa dà, ara rẹ̀ á balẹ̀, kò ní rí ìyọlẹ́nu,
Ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.”+
11 “Nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ,” ni Jèhófà wí, “láti gbà ọ́.
-
-
Ìsíkíẹ́lì 34:13, 14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Èmi yóò mú wọn jáde láàárín àwọn èèyàn, màá sì kó wọn jọ láti àwọn ilẹ̀. Èmi yóò mú wọn wá sórí ilẹ̀ wọn, màá sì bọ́ wọn lórí àwọn òkè Ísírẹ́lì,+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi tó ń ṣàn àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ gbogbo ibi tí wọ́n ń gbé ní ilẹ̀ náà. 14 Èmi yóò bọ́ wọn ní ibi ìjẹko tó dáa, ilẹ̀ tí wọ́n á sì ti máa jẹko yóò wà lórí àwọn òkè gíga Ísírẹ́lì.+ Wọ́n á dùbúlẹ̀ síbẹ̀, níbi ìjẹko tó dáa,+ orí ilẹ̀ tó sì dáa jù lórí àwọn òkè Ísírẹ́lì ni wọ́n á ti máa jẹ ewéko.”
-
-
Émọ́sì 9:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Màá kó àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì tó wà ní ìgbèkùn pa dà,+
Wọ́n á tún àwọn ìlú tó ti di ahoro kọ́, wọ́n á sì máa gbé inú wọn;+
Wọ́n á gbin ọgbà àjàrà, wọ́n á sì mu wáìnì wọn,+
Wọ́n á ṣe ọgbà, wọ́n á sì jẹ èso wọn.’+
15 ‘Màá gbìn wọ́n sórí ilẹ̀ wọn,
A kò sì ní fà wọ́n tu mọ́
Kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn,’+ ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ wí.”
-