ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́sírà 9:6, 7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Mo sọ pé: “Ìwọ Ọlọ́run mi, ojú ń tì mí, ara sì ń tì mí láti gbé ojú mi sókè sí ọ, ìwọ Ọlọ́run mi, nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ti pọ̀ gan-an lórí wa, ẹ̀bi wa sì ti ga dé ọ̀run.+ 7 Láti ọjọ́ àwọn baba ńlá wa ni ẹ̀bi wa ti pọ̀ gan-an títí di òní yìí;+ tìtorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ni o ṣe fi àwa, àwọn ọba wa àti àwọn àlùfáà wa lé àwọn ọba ilẹ̀ míì lọ́wọ́, tí wọ́n fi idà pa wá,+ tí wọ́n kó wa lọ sóko ẹrú,+ tí wọ́n kó ohun ìní wa,+ tí wọ́n sì dójú tì wá bó ṣe rí lónìí yìí.+

  • Nehemáyà 9:26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 “Àmọ́, wọ́n ya aláìgbọràn, wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ọ,+ wọ́n sì kẹ̀yìn sí Òfin rẹ.* Wọ́n pa àwọn wòlíì rẹ tó kìlọ̀ fún wọn láti mú wọn pa dà sọ́dọ̀ rẹ, wọ́n sì hu ìwà àìlọ́wọ̀ tó bùáyà.+

  • Nehemáyà 9:33
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 33 O ò lẹ́bi kankan nínú gbogbo ohun tó dé bá wa, nítorí òótọ́ lo fi bá wa lò; àwa la hùwà burúkú.+

  • Sáàmù 106:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 A ti dẹ́ṣẹ̀ bí àwọn baba ńlá wa;+

      A ti ṣe ohun tí kò dáa; a ti hùwà burúkú.+

  • Ìdárò 3:42
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 42 “A ti dẹ́ṣẹ̀, a ti ṣọ̀tẹ̀,+ ìwọ kò sì tíì dárí jì wá.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́