-
Diutarónómì 28:63, 64Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
63 “Bí inú Jèhófà ṣe dùn nígbà kan láti mú kí nǹkan máa lọ dáadáa fún yín, kí ẹ sì pọ̀ rẹpẹtẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni inú Jèhófà ṣe máa dùn láti pa yín run kó sì pa yín rẹ́; ẹ sì máa pa run kúrò ní ilẹ̀ tí ẹ fẹ́ lọ gbà.
64 “Jèhófà máa tú ọ ká sáàárín gbogbo orílẹ̀-èdè, láti ìkángun kan ayé dé ìkángun kejì ayé,+ o sì máa ní láti sin àwọn ọlọ́run tí wọ́n fi igi àti òkúta ṣe níbẹ̀, àwọn ọlọ́run tí ìwọ àtàwọn baba ńlá rẹ kò mọ̀.+
-
-
Jóṣúà 23:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Àmọ́ bí gbogbo ìlérí tó dáa tí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe fún yín ṣe ṣẹ sí yín lára,+ bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà máa mú gbogbo àjálù tó ṣèlérí* wá sórí yín, ó sì máa pa yín run lórí ilẹ̀ dáradára tí Jèhófà Ọlọ́run yín fún yín.+ 16 Tí ẹ bá da májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run yín tó pa láṣẹ pé kí ẹ máa pa mọ́, tí ẹ bá sì lọ ń sin àwọn ọlọ́run míì, tí ẹ̀ ń forí balẹ̀ fún wọn, Jèhófà máa bínú sí yín gidigidi,+ ẹ sì máa pa run kíákíá lórí ilẹ̀ dáradára tó fún yín.”+
-
-
1 Àwọn Ọba 9:6, 7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Àmọ́ tí ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín bá pa dà lẹ́yìn mi, tí ẹ kò sì pa àwọn àṣẹ àti òfin tí mo fún yín mọ́, tí ẹ wá lọ ń sin àwọn ọlọ́run míì, tí ẹ sì ń forí balẹ̀ fún wọn,+ 7 ṣe ni màá ké Ísírẹ́lì kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn,+ màá gbé ilé tí mo ti yà sí mímọ́ fún orúkọ mi sọ nù kúrò níwájú mi,+ Ísírẹ́lì yóò sì di ẹni ẹ̀gàn* àti ẹni ẹ̀sín láàárín gbogbo èèyàn.+
-