-
Nọ́ńbà 11:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Mósè wá sọ fún Jèhófà pé: “Kí ló dé tí o fìyà jẹ ìránṣẹ́ rẹ? Kí ló dé tí o kò ṣojúure sí mi, tí o sì di ẹrù gbogbo àwọn èèyàn yìí lé mi lórí?+
-
-
Nọ́ńbà 11:15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Tó bá jẹ́ ohun tí o fẹ́ ṣe fún mi nìyí, jọ̀ọ́ kúkú pa mí báyìí.+ Tí mo bá rí ojúure rẹ, má ṣe jẹ́ kí ojú mi tún rí ibi mọ́.”
-
-
Jóòbù 6:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ká ní ọwọ́ mi lè tẹ ohun tí mo béèrè ni,
Kí Ọlọ́run sì ṣe ohun tí mo fẹ́ fún mi!
9 Pé kí Ọlọ́run ṣe tán láti tẹ̀ mí rẹ́,
Kó na ọwọ́ rẹ̀, kó sì pa mí dà nù!+
-