-
2 Àwọn Ọba 3:26, 27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Nígbà tí ọba Móábù rí i pé apá òun ò ká ogun náà mọ́, ó kó ọgọ́rùn-ún méje (700) ọkùnrin tó ń lo idà jọ, kí wọ́n lè kọjá sọ́dọ̀ ọba Édómù;+ àmọ́ wọn ò lè kọjá. 27 Torí náà, ó mú ọmọ rẹ̀ àkọ́bí tó máa jọba ní ipò rẹ̀, ó sì fi rú ẹbọ sísun+ lórí ògiri. Wọ́n bínú sí Ísírẹ́lì gan-an, torí náà, àwọn èèyàn Ísírẹ́lì pa dà lẹ́yìn ọba Móábù, wọ́n sì pa dà sí ilẹ̀ wọn.
-