ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 12:31
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 31 O ò gbọ́dọ̀ ṣe báyìí sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ, torí gbogbo ohun tí Jèhófà kórìíra ni wọ́n máa ń ṣe sí àwọn ọlọ́run wọn, kódà wọ́n máa ń sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná sí àwọn ọlọ́run wọn.+

  • 2 Kíróníkà 28:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 Ẹni ogún (20) ọdún ni Áhásì+ nígbà tó jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Kò ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.+

  • 2 Kíróníkà 28:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Yàtọ̀ síyẹn, ó mú ẹbọ rú èéfín ní Àfonífojì Ọmọ Hínómù,* ó sì sun àwọn ọmọ rẹ̀ nínú iná,+ ó tipa bẹ́ẹ̀ ṣe ohun ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè+ tí Jèhófà lé kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣe.

  • Sáàmù 106:37, 38
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 37 Wọ́n ń fi àwọn ọmọkùnrin wọn

      Àti àwọn ọmọbìnrin wọn rúbọ sí àwọn ẹ̀mí èṣù.+

      38 Wọ́n ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,+

      Ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin wọn àti ti àwọn ọmọbìnrin wọn

      Tí wọ́n fi rúbọ sí àwọn òrìṣà Kénáánì;+

      Ilẹ̀ náà sì di ẹlẹ́gbin nítorí ìtàjẹ̀sílẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́