-
Diutarónómì 12:31Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
31 O ò gbọ́dọ̀ ṣe báyìí sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ, torí gbogbo ohun tí Jèhófà kórìíra ni wọ́n máa ń ṣe sí àwọn ọlọ́run wọn, kódà wọ́n máa ń sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná sí àwọn ọlọ́run wọn.+
-
-
2 Àwọn Ọba 16:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Ní ọdún kẹtàdínlógún Pékà ọmọ Remaláyà, Áhásì+ ọmọ Jótámù ọba Júdà di ọba.
-
-
2 Àwọn Ọba 17:17, 18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Wọ́n tún ń sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná,+ wọ́n ń woṣẹ́,+ wọ́n ń wá àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀, wọ́n pinnu* láti máa ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú un bínú.
18 Nítorí náà, inú bí Jèhófà gidigidi sí Ísírẹ́lì, tí ó fi mú wọn kúrò níwájú rẹ̀.+ Kò jẹ́ kí èyíkéyìí ṣẹ́ kù lára wọn àfi ẹ̀yà Júdà nìkan.
-
-
Jeremáyà 7:30, 31Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 ‘Nítorí àwọn èèyàn Júdà ti ṣe ohun tó burú ní ojú mi,’ ni Jèhófà wí. ‘Wọ́n ti gbé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn kalẹ̀ sínú ilé tí a fi orúkọ mi pè, láti sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin.+ 31 Wọ́n ti kọ́ àwọn ibi gíga Tófétì, èyí tó wà ní Àfonífojì Ọmọ Hínómù,*+ láti sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná,+ ohun tí mi ò pa láṣẹ, tí kò sì wá sí mi lọ́kàn rí.’*+
-