-
1 Àwọn Ọba 16:25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Ómírì ń ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà nígbà gbogbo, tiẹ̀ tún burú ju ti gbogbo àwọn tó ṣáájú rẹ̀.+
-
-
1 Àwọn Ọba 16:30Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 Ìwà Áhábù ọmọ Ómírì tún wá burú lójú Jèhófà ju ti gbogbo àwọn tí ó wà ṣáájú rẹ̀.+
-
-
2 Àwọn Ọba 16:2, 3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Ẹni ogún (20) ọdún ni Áhásì nígbà tó jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Kò ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.+ 3 Kàkà bẹ́ẹ̀, ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì,+ kódà ó sun ọmọ rẹ̀ nínú iná,+ ó tipa bẹ́ẹ̀ ṣe ohun ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè+ tí Jèhófà lé kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣe.
-