-
2 Àwọn Ọba 23:26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Síbẹ̀, Jèhófà kò dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ tó ń jó bí iná lórí Júdà nítorí gbogbo ohun búburú tí Mánásè ti ṣe láti mú un bínú.+
-
-
2 Kíróníkà 36:16, 17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Ṣùgbọ́n wọ́n ń fi àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ṣẹ̀sín,+ wọn ò ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí,+ wọ́n sì ń fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́,+ títí ìbínú Jèhófà fi ru sí àwọn èèyàn rẹ̀,+ tí ọ̀rọ̀ wọn sì kọjá àtúnṣe.
17 Nítorí náà, ó gbé ọba àwọn ará Kálídíà+ dìde sí wọn, ẹni tó fi idà pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn+ nínú ibi mímọ́ wọn;+ kò ṣàánú ọ̀dọ́kùnrin tàbí ọ̀dọ́bìnrin,* arúgbó tàbí aláàárẹ̀.+ Ohun gbogbo ni Ọlọ́run fi lé e lọ́wọ́.+
-
-
Jeremáyà 23:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Ìbínú Jèhófà kò ní dáwọ́ dúró
Títí á fi ṣe ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀, tí á sì mú èrò rẹ̀ ṣẹ.
Ní àkókò òpin, ọ̀rọ̀ yìí á yé yín dáadáa.
-