ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 2:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 Á sọ pé: “Èmi fúnra mi ti fi ọba mi jẹ+

      Lórí Síónì,+ òkè mímọ́ mi.”

  • Àìsáyà 32:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 32 Wò ó! Ọba+ kan máa jẹ fún òdodo,+

      Àwọn ìjòyè sì máa ṣàkóso fún ìdájọ́ òdodo.

  • Jeremáyà 23:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 “Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “tí màá gbé èéhù* kan tó jẹ́ olódodo dìde fún Dáfídì.+ Ọba kan máa jẹ,+ á sì fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà, á dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, á sì ṣe òdodo ní ilẹ̀ náà.+

  • Lúùkù 19:37, 38
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 37 Gbàrà tó dé tòsí ojú ọ̀nà tó lọ sísàlẹ̀ láti Òkè Ólífì, inú gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ bẹ̀rẹ̀ sí í dùn, wọ́n sì gbóhùn sókè, wọ́n ń yin Ọlọ́run torí gbogbo iṣẹ́ agbára tí wọ́n ti rí, 38 wọ́n ń sọ pé: “Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ bí Ọba ní orúkọ Jèhófà!* Àlàáfíà ní ọ̀run àti ògo ní ibi gíga lókè!”+

  • Jòhánù 1:49
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 49 Nàtáníẹ́lì dá a lóhùn pé: “Rábì, ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run, ìwọ ni Ọba Ísírẹ́lì.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́