-
Sáàmù 22:27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Gbogbo ayé á rántí, wọ́n á sì yíjú sọ́dọ̀ Jèhófà.
Gbogbo ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè á tẹrí ba níwájú rẹ.+
-
-
Sekaráyà 8:22, 23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Ọ̀pọ̀ èèyàn àti orílẹ̀-èdè alágbára yóò wá sí Jerúsálẹ́mù láti wá Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,+ kí wọ́n sì lè bẹ Jèhófà pé kó ṣojúure sí àwọn.’*
23 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Ní àwọn ọjọ́ yẹn, ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè+ yóò di aṣọ* Júù* kan mú, àní wọn yóò dì í mú ṣinṣin, wọ́n á sì sọ pé: “A fẹ́ bá yín lọ,+ torí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.”’”+
-