ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Máàkù 5:22-24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Ọ̀kan nínú àwọn alága sínágọ́gù, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jáírù wá, nígbà tó sì tajú kán rí i, ó wólẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀.+ 23 Ó bẹ̀ ẹ́ léraléra, ó ní: “Ọmọbìnrin mi kékeré ń ṣàìsàn gidigidi.* Jọ̀ọ́, wá gbé ọwọ́ rẹ lé e+ kí ara rẹ̀ lè yá, kó má sì kú.” 24 Jésù wá tẹ̀ lé e, èrò rẹpẹtẹ sì ń rọ́ tẹ̀ lé e, wọ́n fún mọ́ ọn.

  • Lúùkù 8:41, 42
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 41 Àmọ́ wò ó! ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jáírù wá; ọkùnrin yìí ni alága sínágọ́gù. Ó wólẹ̀ síbi ẹsẹ̀ Jésù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́ pé kó wá sí ilé òun,+ 42 torí pé ọmọbìnrin kan ṣoṣo tó bí,* tó jẹ́ nǹkan bí ọmọ ọdún méjìlá (12), ń kú lọ.

      Bí Jésù ṣe ń lọ, àwọn èrò ń fún mọ́ ọn.

  • Jòhánù 11:25
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 Jésù sọ fún un pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè.+ Ẹni tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú mi, tó bá tiẹ̀ kú, ó máa yè;

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́