-
Máàkù 5:22-24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Ọ̀kan nínú àwọn alága sínágọ́gù, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jáírù wá, nígbà tó sì tajú kán rí i, ó wólẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀.+ 23 Ó bẹ̀ ẹ́ léraléra, ó ní: “Ọmọbìnrin mi kékeré ń ṣàìsàn gidigidi.* Jọ̀ọ́, wá gbé ọwọ́ rẹ lé e+ kí ara rẹ̀ lè yá, kó má sì kú.” 24 Jésù wá tẹ̀ lé e, èrò rẹpẹtẹ sì ń rọ́ tẹ̀ lé e, wọ́n fún mọ́ ọn.
-