41 Àmọ́ wò ó! ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jáírù wá; ọkùnrin yìí ni alága sínágọ́gù. Ó wólẹ̀ síbi ẹsẹ̀ Jésù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́ pé kó wá sí ilé òun,+ 42 torí pé ọmọbìnrin kan ṣoṣo tó bí, tó jẹ́ nǹkan bí ọmọ ọdún méjìlá (12), ń kú lọ.
Bí Jésù ṣe ń lọ, àwọn èrò ń fún mọ́ ọn.