42 Wò ó! Ìránṣẹ́ mi,+ tí mò ń tì lẹ́yìn!
Àyànfẹ́ mi,+ ẹni tí mo tẹ́wọ́ gbà!+
Mo ti fi ẹ̀mí mi sínú rẹ̀;+
Ó máa mú ìdájọ́ òdodo wá fún àwọn orílẹ̀-èdè.+
2 Kò ní ké jáde tàbí kó gbé ohùn rẹ̀ sókè,
Kò sì ní jẹ́ ká gbọ́ ohùn rẹ̀ lójú ọ̀nà.+
3 Kò ní ṣẹ́ esùsú kankan tó ti fọ́,
Kò sì ní pa òwú àtùpà kankan tó ń jó lọ́úlọ́ú tí wọ́n fi ọ̀gbọ̀ ṣe.+
Ó máa fi òótọ́ ṣe ìdájọ́ òdodo.+
4 Kò ní rẹ̀ ẹ́, a ò sì ní tẹ̀ ẹ́ rẹ́ títí ó fi máa fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀ ní ayé;+
Àwọn erékùṣù sì ń dúró de òfin rẹ̀.