-
Máàkù 3:22-27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Bákan náà, àwọn akọ̀wé òfin, tí wọ́n wá láti Jerúsálẹ́mù ń sọ pé: “Ó ní Béélísébúbù,* agbára alákòóso àwọn ẹ̀mí èṣù ló sì fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”+ 23 Torí náà, lẹ́yìn tó pè wọ́n sọ́dọ̀, ó fi àwọn àpèjúwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé: “Báwo ni Sátánì ṣe lè lé Sátánì jáde? 24 Tí ìjọba kan bá pínyà sí ara rẹ̀, ìjọba yẹn ò ní lè dúró;+ 25 tí ilé kan bá sì pínyà sí ara rẹ̀, ilé yẹn ò ní lè dúró. 26 Bákan náà, tí Sátánì bá dìde, tó ta ko ara rẹ̀, tó sì pínyà, kò ní lè dúró, ṣe ló máa pa run. 27 Àní, kò sí ẹni tó lè wọ ilé ọkùnrin alágbára, tó máa lè jí àwọn ohun ìní rẹ̀, àfi tó bá kọ́kọ́ de ọkùnrin alágbára náà mọ́lẹ̀. Ìgbà yẹn ló máa tó lè kó o lẹ́rù nínú ilé rẹ̀.
-
-
Lúùkù 11:15-23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Àmọ́ àwọn kan nínú wọn sọ pé: “Agbára Béélísébúbù,* alákòóso àwọn ẹ̀mí èṣù, ló fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”+ 16 Kí àwọn míì sì lè dán an wò, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún un pé kó fi àmì kan+ láti ọ̀run han àwọn. 17 Ó mọ ohun tí wọ́n ń rò,+ ó wá sọ fún wọn pé: “Gbogbo ìjọba tó bá pínyà sí ara rẹ̀ máa pa run, ilé tó bá sì pínyà sí ara rẹ̀ máa wó. 18 Lọ́nà kan náà, tí Sátánì náà bá pínyà sí ara rẹ̀, báwo ni ìjọba rẹ̀ ṣe máa dúró? Torí ẹ sọ pé Béélísébúbù ni mo fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. 19 Tó bá jẹ́ agbára Béélísébúbù ni mo fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, agbára ta ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde? Ìdí nìyí tí wọ́n fi máa jẹ́ adájọ́ yín. 20 Àmọ́ tó bá jẹ́ ìka Ọlọ́run + ni mo fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, Ìjọba Ọlọ́run ti dé bá yín lójijì lóòótọ́.+ 21 Tí ọkùnrin alágbára kan, tó dira ogun dáadáa, bá ń ṣọ́ ààfin rẹ̀, kò sóhun tó máa ṣe àwọn ohun ìní rẹ̀. 22 Àmọ́ tí ẹnì kan tó lágbára jù ú lọ bá wá gbéjà kò ó, tó sì ṣẹ́gun rẹ̀, ẹni yẹn máa kó gbogbo ohun ìjà rẹ̀ tó gbẹ́kẹ̀ lé lọ, á sì pín àwọn ohun tó kó lọ́dọ̀ rẹ̀. 23 Ẹnikẹ́ni tí kò bá sí lọ́dọ̀ mi ń ta kò mí, ẹnikẹ́ni tí kò bá sì dara pọ̀ mọ́ mi ń fọ́n ká.+
-