ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Dáníẹ́lì 7:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 A sì fún un ní àkóso,+ ọlá+ àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn èèyàn, orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà máa sìn ín.+ Àkóso rẹ̀ jẹ́ àkóso tó máa wà títí láé, tí kò ní kọjá lọ, ìjọba rẹ̀ ò sì ní pa run.+

  • Mátíù 20:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Ó sọ fún obìnrin náà pé: “Kí lo fẹ́?” Ó fèsì pé: “Pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ mi méjèèjì yìí jókòó, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti ọ̀kan ní òsì rẹ, nínú Ìjọba rẹ.”+

  • Lúùkù 22:28-30
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin lẹ ti dúró tì mí+ nígbà àdánwò;+ 29 mo sì bá yín dá májẹ̀mú fún ìjọba kan, bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú,+ 30 kí ẹ lè máa jẹ, kí ẹ sì máa mu ní tábìlì mi nínú Ìjọba mi,+ kí ẹ sì jókòó lórí ìtẹ́+ láti ṣèdájọ́ ẹ̀yà méjìlá (12) Ísírẹ́lì.+

  • 1 Kọ́ríńtì 6:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 Àbí ẹ ò mọ̀ pé àwọn ẹni mímọ́ ló máa ṣèdájọ́ ayé?+ Tó bá sì jẹ́ pé ẹ̀yin lẹ máa ṣèdájọ́ ayé, ṣé ẹ ò mọ bí ẹ ṣe máa gbọ́ ẹjọ́ lórí àwọn ọ̀ràn tí kò tó nǹkan ni?

  • Ìfihàn 20:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Mo rí àwọn ìtẹ́, a sì fún àwọn tó jókòó sórí wọn ní agbára láti ṣèdájọ́. Kódà, mo rí ọkàn* àwọn tí wọ́n pa* torí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́ nípa Jésù, tí wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti àwọn tí kò jọ́sìn ẹranko náà tàbí ère rẹ̀, tí wọn ò sì gba àmì náà síwájú orí wọn àti ọwọ́ wọn.+ Wọ́n pa dà wà láàyè, wọ́n sì jọba pẹ̀lú Kristi+ fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́