-
Máàkù 10:46-52Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
46 Wọ́n wá dé Jẹ́ríkò. Àmọ́ bí òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń kúrò ní Jẹ́ríkò, Báátíméù (ọmọ Tíméù), afọ́jú tó ń ṣe agbe, jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà.+ 47 Nígbà tó gbọ́ pé Jésù ará Násárẹ́tì ni, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe, ó sì ń sọ pé: “Ọmọ Dáfídì,+ Jésù, ṣàánú mi!”+ 48 Ni ọ̀pọ̀ èèyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí, wọ́n ní kó dákẹ́, àmọ́ ṣe ló túbọ̀ ń kígbe pé: “Ọmọ Dáfídì, ṣàánú mi!” 49 Torí náà, Jésù dúró, ó sì sọ pé: “Ẹ pè é wá sọ́dọ̀ mi.” Wọ́n wá pe ọkùnrin afọ́jú náà, wọ́n sọ fún un pé: “Mọ́kàn le! Dìde; ó ń pè ọ́.” 50 Ló bá bọ́ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ dà nù, ó fò dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Jésù. 51 Jésù wá sọ fún un pé: “Kí lo fẹ́ kí n ṣe fún ọ?” Ọkùnrin afọ́jú náà sọ fún un pé: “Rábónì,* jẹ́ kí n pa dà ríran.” 52 Jésù sì sọ fún un pé: “Máa lọ. Ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó pa dà ríran,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé e lójú ọ̀nà.
-
-
Lúùkù 18:35-43Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
35 Bí Jésù ṣe ń sún mọ́ Jẹ́ríkò, ọkùnrin afọ́jú kan jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, ó ń ṣagbe.+ 36 Torí ó gbọ́ ariwo èrò tó ń kọjá lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wádìí ohun tó ń ṣẹlẹ̀. 37 Wọ́n sọ fún un pé: “Jésù ará Násárẹ́tì ló ń kọjá lọ!” 38 Ló bá kígbe pé: “Jésù, Ọmọ Dáfídì, ṣàánú mi!” 39 Àwọn tó wà níwájú sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí, wọ́n ní kó dákẹ́, àmọ́ ṣe ló túbọ̀ ń kígbe pé: “Ọmọ Dáfídì, ṣàánú mi!” 40 Jésù wá dúró, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú ọkùnrin náà wá sọ́dọ̀ òun. Lẹ́yìn tó sún mọ́ tòsí, Jésù bi í pé: 41 “Kí lo fẹ́ kí n ṣe fún ọ?” Ó sọ pé: “Olúwa, jẹ́ kí n pa dà ríran.” 42 Jésù wá sọ fún un pé: “Kí ojú rẹ pa dà ríran; ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.”+ 43 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó pa dà ríran, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé e,+ ó ń yin Ọlọ́run lógo. Bákan náà, gbogbo èèyàn yin Ọlọ́run nígbà tí wọ́n rí èyí.+
-