ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Mátíù 10:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Ẹ máa ṣọ́ra yín lọ́dọ̀ àwọn èèyàn; torí wọ́n máa fà yín lé àwọn ilé ẹjọ́ àdúgbò lọ́wọ́,+ wọ́n á sì nà yín+ nínú àwọn sínágọ́gù wọn.+

  • Mátíù 10:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Gbogbo èèyàn sì máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi,+ ṣùgbọ́n ẹni tó bá fara dà á* dé òpin máa rí ìgbàlà.+

  • Máàkù 13:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 “Ní tiyín, ẹ máa ṣọ́ra yín. Àwọn èèyàn máa fà yín lé àwọn ilé ẹjọ́ àdúgbò lọ́wọ́,+ wọ́n máa lù yín nínú àwọn sínágọ́gù,+ ẹ sì máa dúró níwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba nítorí mi, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún wọn.+

  • Máàkù 13:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Gbogbo èèyàn sì máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi.+ Àmọ́ ẹni tó bá fara dà á* dé òpin+ máa rí ìgbàlà.+

  • Lúùkù 21:12, 13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 “Àmọ́ kí gbogbo àwọn nǹkan yìí tó ṣẹlẹ̀, àwọn èèyàn máa gbé ọwọ́ wọn lé yín, wọ́n á sì ṣe inúnibíni sí yín,+ wọ́n á fà yín lé àwọn sínágọ́gù lọ́wọ́, wọ́n á sì fi yín sẹ́wọ̀n. Wọ́n máa mú yín lọ síwájú àwọn ọba àti àwọn gómìnà nítorí orúkọ mi.+ 13 Èyí máa jẹ́ kí ẹ lè jẹ́rìí.

  • Lúùkù 21:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 gbogbo èèyàn sì máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi.+

  • Jòhánù 15:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Àmọ́ wọ́n máa ṣe gbogbo nǹkan yìí sí yín nítorí orúkọ mi, torí pé wọn ò mọ Ẹni tó rán mi.+

  • 2 Tímótì 3:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Ó dájú pé gbogbo àwọn tó bá fẹ́ fi ayé wọn sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù ni wọ́n máa ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́