-
Máàkù 13:14-18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 “Àmọ́ tí ẹ bá tajú kán rí ohun ìríra tó ń fa ìsọdahoro,+ tó dúró ní ibi tí kò yẹ (kí òǹkàwé lo òye), nígbà náà, kí àwọn tó wà ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àwọn òkè.+ 15 Kí ẹni tó wà lórí ilé má sọ̀ kalẹ̀ tàbí kó wọlé lọ mú ohunkóhun kúrò nínú ilé rẹ̀; 16 kí ẹni tó wà ní pápá má sì pa dà sí àwọn ohun tó wà lẹ́yìn láti mú aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀. 17 Ó mà ṣe o, fún àwọn aláboyún àti àwọn tó ń tọ́ ọmọ jòjòló ní àwọn ọjọ́ yẹn o!+ 18 Ẹ máa gbàdúrà kó má lọ bọ́ sí ìgbà òtútù;
-