Diutarónómì 8:3 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 3 Torí náà, ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀, ó jẹ́ kí ebi pa ọ́,+ ó sì fi mánà bọ́ ọ,+ oúnjẹ tí o kò mọ̀, tí àwọn bàbá rẹ ò sì mọ̀, kí o lè mọ̀ pé kì í ṣe oúnjẹ nìkan ṣoṣo ló ń mú kí èèyàn wà láàyè, àmọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu Jèhófà jáde ni èèyàn fi ń wà láàyè.+ Lúùkù 4:4 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 4 Àmọ́ Jésù dá a lóhùn pé: “A ti kọ ọ́ pé, ‘Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ṣoṣo ló ń mú kí èèyàn wà láàyè.’”+ Jòhánù 4:34 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 34 Jésù sọ fún wọn pé: “Oúnjẹ mi ni pé kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tó rán mi,+ kí n sì parí iṣẹ́ rẹ̀.+
3 Torí náà, ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀, ó jẹ́ kí ebi pa ọ́,+ ó sì fi mánà bọ́ ọ,+ oúnjẹ tí o kò mọ̀, tí àwọn bàbá rẹ ò sì mọ̀, kí o lè mọ̀ pé kì í ṣe oúnjẹ nìkan ṣoṣo ló ń mú kí èèyàn wà láàyè, àmọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu Jèhófà jáde ni èèyàn fi ń wà láàyè.+