21 Lẹ́yìn tí Jésù sọ àwọn nǹkan yìí, ẹ̀dùn ọkàn bá a nínú ẹ̀mí, ó sì jẹ́rìí, ó sọ pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ọ̀kan nínú yín máa dà mí.”+ 22 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá bẹ̀rẹ̀ sí í wo ara wọn, torí ọ̀rọ̀ náà rú wọn lójú, wọn ò mọ ẹni tó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.+