27 Jésù sì sọ fún wọn pé: “Gbogbo yín lẹ máa kọsẹ̀, torí a ti kọ ọ́ pé: ‘Màá kọ lu olùṣọ́ àgùntàn,+ àwọn àgùntàn sì máa tú ká.’+28 Àmọ́ lẹ́yìn tí mo bá jíǹde, màá lọ sí Gálílì ṣáájú yín.”+
32 Ẹ wò ó! Wákàtí náà ń bọ̀, ní tòótọ́, ó ti dé, nígbà tí wọ́n máa tú ẹnì kọ̀ọ̀kan yín ká sí ilé rẹ̀, ẹ sì máa fi èmi nìkan sílẹ̀.+ Àmọ́ mi ò dá wà, torí pé Baba wà pẹ̀lú mi.+