-
Mátíù 26:31-33Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
31 Jésù sọ fún wọn pé: “Gbogbo yín lẹ máa kọsẹ̀ torí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí mi lóru òní, torí a ti kọ ọ́ pé: ‘Màá kọ lu olùṣọ́ àgùntàn, àwọn àgùntàn inú agbo sì máa tú ká.’+ 32 Àmọ́ lẹ́yìn tí mo bá jíǹde, màá lọ sí Gálílì ṣáájú yín.”+ 33 Ṣùgbọ́n Pétérù dá a lóhùn pé: “Tí gbogbo àwọn yòókù bá tiẹ̀ kọsẹ̀ torí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ọ, ó dájú pé èmi ò ní kọsẹ̀ láé!”+
-
-
Máàkù 14:50Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
50 Gbogbo wọn fi í sílẹ̀, wọ́n sì sá lọ.+
-