ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Máàkù 14:66-72
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 66 Nígbà tí Pétérù wà nísàlẹ̀ nínú àgbàlá, ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́bìnrin àlùfáà àgbà wá.+ 67 Bó ṣe rí Pétérù tó ń yáná, ó tẹjú mọ́ ọn, ó sì sọ pé: “Ìwọ náà wà pẹ̀lú Jésù ará Násárẹ́tì yìí.” 68 Àmọ́ ó sẹ́, ó ní: “Mi ò mọ̀ ọ́n, ohun tí ò ń sọ ò sì yé mi,” ló bá jáde lọ sí ibi àbáwọlé.* 69 Ìránṣẹ́bìnrin náà rí i níbẹ̀, ló bá tún bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn tó dúró nítòsí pé: “Ọ̀kan lára wọn nìyí.” 70 Ó tún ń sẹ́. Lẹ́yìn tó ṣe díẹ̀, àwọn tó dúró nítòsí tún bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún Pétérù pé: “Ó dájú pé o wà lára wọn, torí ká sòótọ́, ará Gálílì ni ọ́.” 71 Àmọ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í gégùn-ún, ó sì ń búra pé: “Mi ò mọ ọkùnrin tí ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí!” 72 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àkùkọ kọ lẹ́ẹ̀kejì,+ Pétérù sì rántí ohun tí Jésù sọ fún un pé: “Kí àkùkọ tó kọ lẹ́ẹ̀mejì, o máa sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹta.”+ Ló bá bara jẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún.

  • Lúùkù 22:54-62
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 54 Wọ́n wá fàṣẹ ọba mú un, wọ́n sì mú un lọ,+ wọ́n mú un wá sínú ilé àlùfáà àgbà; àmọ́ Pétérù ń tẹ̀ lé wọn ní òkèèrè.+ 55 Nígbà tí wọ́n dáná láàárín àgbàlá, tí wọ́n sì jọ jókòó, Pétérù jókòó láàárín wọn.+ 56 Àmọ́ ìránṣẹ́bìnrin kan rí i tó jókòó síbi iná náà, ó wò ó dáadáa, ó sì sọ pé: “Ọkùnrin yìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀.” 57 Àmọ́ ó sẹ́, ó ní: “Ìwọ obìnrin yìí, mi ò mọ̀ ọ́n.” 58 Nígbà tó ṣe díẹ̀, ẹlòmíì rí i, ó sì sọ pé: “Ìwọ náà wà lára wọn.” Àmọ́ Pétérù sọ pé: “Wò ó ọkùnrin yìí, mi ò sí lára wọn.”+ 59 Lẹ́yìn nǹkan bíi wákàtí kan, ọkùnrin míì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹnu mọ́ ọn pé: “Ó dájú pé ọkùnrin yìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀, torí ká sòótọ́, ará Gálílì ni!” 60 Àmọ́ Pétérù sọ pé: “Ìwọ ọkùnrin yìí, mi ò mọ ohun tó ò ń sọ.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, àkùkọ kọ. 61 Ni Olúwa bá yíjú pa dà, ó sì wo Pétérù tààràtà, Pétérù wá rántí ohun tí Olúwa sọ fún un pé: “Kí àkùkọ tó kọ lónìí, o máa sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹta.”+ 62 Ló bá bọ́ síta, ó sì sunkún gidigidi.

  • Jòhánù 18:15-17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Símónì Pétérù àti ọmọ ẹ̀yìn míì ń tẹ̀ lé Jésù.+ Àlùfáà àgbà mọ ọmọ ẹ̀yìn yẹn, ó sì bá Jésù lọ sínú àgbàlá àlùfáà àgbà, 16 àmọ́ Pétérù dúró síta níbi ilẹ̀kùn.* Torí náà, ọmọ ẹ̀yìn kejì, tí àlùfáà àgbà mọ̀, jáde lọ bá aṣọ́nà sọ̀rọ̀, ó sì mú Pétérù wọlé. 17 Ìránṣẹ́bìnrin tó jẹ́ aṣọ́nà wá sọ fún Pétérù pé: “Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ọkùnrin yìí ni ọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?” Ó sọ pé: “Rárá o.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́