-
Mátíù 26:69-75Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
69 Pétérù jókòó síta nínú àgbàlá, ìránṣẹ́bìnrin kan sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní: “Ìwọ náà wà pẹ̀lú Jésù ará Gálílì!”+ 70 Àmọ́ ó sẹ́ níwájú gbogbo wọn, ó ní: “Mi ò mọ ohun tí ò ń sọ.” 71 Nígbà tó jáde lọ sí ilé ẹnu ọ̀nà, ọmọbìnrin míì tún kíyè sí i, ó sì sọ fún àwọn tó wà níbẹ̀ pé: “Ọkùnrin yìí wà pẹ̀lú Jésù ará Násárẹ́tì.”+ 72 Ló bá tún sẹ́, ó sì búra pé: “Mi ò mọ ọkùnrin náà!” 73 Lẹ́yìn tó ṣe díẹ̀, àwọn tó dúró sí àyíká wá, wọ́n sì sọ fún Pétérù pé: “Ó dájú pé ìwọ náà wà lára wọn, torí ká sòótọ́, èdè ẹnu rẹ* tú ọ fó.” 74 Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í gégùn-ún, ó sì ń búra pé: “Mi ò mọ ọkùnrin náà!” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àkùkọ kọ. 75 Pétérù wá rántí ohun tí Jésù sọ, pé: “Kí àkùkọ tó kọ, o máa sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹta.”+ Ló bá bọ́ síta, ó sì sunkún gidigidi.
-
-
Lúùkù 22:55-62Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
55 Nígbà tí wọ́n dáná láàárín àgbàlá, tí wọ́n sì jọ jókòó, Pétérù jókòó láàárín wọn.+ 56 Àmọ́ ìránṣẹ́bìnrin kan rí i tó jókòó síbi iná náà, ó wò ó dáadáa, ó sì sọ pé: “Ọkùnrin yìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀.” 57 Àmọ́ ó sẹ́, ó ní: “Ìwọ obìnrin yìí, mi ò mọ̀ ọ́n.” 58 Nígbà tó ṣe díẹ̀, ẹlòmíì rí i, ó sì sọ pé: “Ìwọ náà wà lára wọn.” Àmọ́ Pétérù sọ pé: “Wò ó ọkùnrin yìí, mi ò sí lára wọn.”+ 59 Lẹ́yìn nǹkan bíi wákàtí kan, ọkùnrin míì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹnu mọ́ ọn pé: “Ó dájú pé ọkùnrin yìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀, torí ká sòótọ́, ará Gálílì ni!” 60 Àmọ́ Pétérù sọ pé: “Ìwọ ọkùnrin yìí, mi ò mọ ohun tó ò ń sọ.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, àkùkọ kọ. 61 Ni Olúwa bá yíjú pa dà, ó sì wo Pétérù tààràtà, Pétérù wá rántí ohun tí Olúwa sọ fún un pé: “Kí àkùkọ tó kọ lónìí, o máa sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹta.”+ 62 Ló bá bọ́ síta, ó sì sunkún gidigidi.
-