9 Ẹ má ṣe wá wúrà, fàdákà tàbí bàbà sínú àmùrè tí ẹ̀ ń kó owó sí,+10 tàbí àpò oúnjẹ fún ìrìn àjò náà tàbí aṣọ méjì,* bàtà tàbí ọ̀pá,+ torí oúnjẹ tọ́ sí òṣìṣẹ́.+
8 Ó tún pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe gbé ohunkóhun dání fún ìrìn àjò náà, àfi ọ̀pá, kí wọ́n má ṣe gbé oúnjẹ àti àpò oúnjẹ, kí wọ́n má sì kó owó* sínú àmùrè owó wọn,+9 àmọ́ kí wọ́n wọ bàtà, kí wọ́n má sì wọ aṣọ méjì.*