-
Mátíù 17:1-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Ọjọ́ mẹ́fà lẹ́yìn náà, Jésù mú Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀ dání lọ sí orí òkè kan tó ga fíofío láwọn nìkan.+ 2 A sì yí i pa dà di ológo níwájú wọn; ojú rẹ̀ tàn bí oòrùn, aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ sì tàn yòò* bí ìmọ́lẹ̀.+ 3 Wò ó! Mósè àti Èlíjà fara hàn wọ́n níbẹ̀, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀. 4 Pétérù wá sọ fún Jésù pé: “Olúwa, ó dáa bí a ṣe wà níbí. Tí o bá fẹ́, màá pa àgọ́ mẹ́ta síbí, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mósè àti ọ̀kan fún Èlíjà.” 5 Bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, wò ó! ìkùukùu* tó mọ́lẹ̀ yòò ṣíji bò wọ́n, sì wò ó! ohùn kan dún látinú ìkùukùu náà pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.+ Ẹ fetí sí i.”+ 6 Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà dojú bolẹ̀, ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. 7 Jésù wá sún mọ́ wọn, ó fọwọ́ kàn wọ́n, ó sì sọ pé: “Ẹ dìde. Ẹ má bẹ̀rù.” 8 Nígbà tí wọ́n gbójú sókè, wọn ò rí ẹnì kankan àfi Jésù nìkan.
-
-
Máàkù 9:2-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Ọjọ́ mẹ́fà lẹ́yìn náà, Jésù mú Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù dání lọ sí orí òkè kan tó ga fíofío láwọn nìkan. A sì yí i pa dà di ológo níwájú wọn;+ 3 aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tàn yinrin, ó di funfun nini ju bí alágbàfọ̀ èyíkéyìí ní ayé ṣe lè sọ ọ́ di funfun. 4 Bákan náà, Èlíjà àti Mósè fara hàn wọ́n, wọ́n sì ń bá Jésù sọ̀rọ̀. 5 Pétérù wá sọ fún Jésù pé: “Rábì, ó dáa bí a ṣe wà níbí. Torí náà, jẹ́ ká pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mósè àti ọ̀kan fún Èlíjà.” 6 Ní tòótọ́, kò mọ ohun tí ì bá ṣe, torí ẹ̀rù bà wọ́n gan-an. 7 Ìkùukùu* wá kóra jọ, ó ṣíji bò wọ́n, ohùn kan+ sì dún látinú ìkùukùu náà pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́.+ Ẹ fetí sí i.”+ 8 Lójijì, wọ́n wò yí ká, wọn ò sì rí ẹnì kankan pẹ̀lú wọn mọ́, àfi Jésù nìkan.
-