ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Mátíù 6:25-30
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 “Torí náà, mo sọ fún yín pé: Ẹ yéé ṣàníyàn+ nípa ẹ̀mí* yín, ní ti ohun tí ẹ máa jẹ tàbí tí ẹ máa mu tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ máa wọ̀.+ Ṣé ẹ̀mí* ò ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ ni, tí ara sì ṣe pàtàkì ju aṣọ lọ?+ 26 Ẹ fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run;+ wọn kì í fúnrúgbìn tàbí kárúgbìn tàbí kí wọ́n kó nǹkan jọ sínú ilé ìkẹ́rùsí, síbẹ̀ Baba yín ọ̀run ń bọ́ wọn. Ṣé ẹ ò wá níye lórí jù wọ́n lọ ni? 27 Èwo nínú yín ló lè fi ìgbọ̀nwọ́* kan kún ìwàláàyè rẹ̀, tó bá ń ṣàníyàn?+ 28 Bákan náà, kí ló dé tí ẹ̀ ń ṣàníyàn nípa ohun tí ẹ máa wọ̀? Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn òdòdó lílì inú pápá, bí wọ́n ṣe ń dàgbà; wọn kì í ṣe làálàá, wọn kì í sì í rànwú;* 29 àmọ́ mò ń sọ fún yín pé, a ò ṣe Sólómọ́nì+ pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ bí ọ̀kan lára àwọn yìí. 30 Tó bá jẹ́ pé báyìí ni Ọlọ́run ṣe ń wọ ewéko pápá láṣọ, tó wà lónìí, tí a sì sọ sínú ààrò lọ́la, ṣé kò wá ní wọ̀ yín láṣọ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré?

  • Fílípì 4:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun,+ àmọ́ nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run;+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́