32 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé gbogbo ẹni tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, tí kò bá jẹ́ torí ìṣekúṣe,* lè mú kí obìnrin náà ṣe àgbèrè, ẹnikẹ́ni tó bá sì fẹ́ obìnrin tí wọ́n ti kọ̀ sílẹ̀ ti ṣe àgbèrè.+
11 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, tó sì fẹ́ ẹlòmíì ti ṣe àgbèrè,+ ó ti da obìnrin náà, 12 tí obìnrin kan bá sì lọ fẹ́ ọkùnrin míì, lẹ́yìn tó kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, ó ti ṣe àgbèrè.”+