11 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, tó sì fẹ́ ẹlòmíì ti ṣe àgbèrè,+ ó ti da obìnrin náà, 12 tí obìnrin kan bá sì lọ fẹ́ ọkùnrin míì, lẹ́yìn tó kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, ó ti ṣe àgbèrè.”+
3 Torí náà, nígbà tí ọkọ rẹ̀ bá wà láàyè, a ó pè é ní alágbèrè obìnrin tó bá fẹ́ ọkùnrin míì.+ Àmọ́ tí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin rẹ̀, kì í sì í ṣe alágbèrè obìnrin tó bá fẹ́ ọkùnrin míì.+