8 Ó sọ pé: “Ẹ ṣọ́ra kí wọ́n má bàa ṣì yín lọ́nà;+ torí ọ̀pọ̀ èèyàn máa wá ní orúkọ mi, wọ́n á sọ pé, ‘Èmi ni ẹni náà’ àti pé, ‘Àkókò náà ti sún mọ́lé.’ Ẹ má tẹ̀ lé wọn.+
4Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ má gba gbogbo ọ̀rọ̀ onímìísí*+ gbọ́, àmọ́ kí ẹ dán àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí* wò kí ẹ lè mọ̀ bóyá ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló ti wá,+ torí ọ̀pọ̀ wòlíì èké ló ti jáde lọ sínú ayé.+