23 “Nígbà yẹn, tí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín pé, ‘Wò ó! Kristi wà níbí’+ tàbí ‘Lọ́hùn-ún!’ ẹ má gbà á gbọ́.+ 24 Torí àwọn èké Kristi àti àwọn wòlíì èké+ máa dìde, wọ́n sì máa ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu tó lágbára, láti ṣi àwọn àyànfẹ́ pàápàá lọ́nà,+ tó bá ṣeé ṣe.