-
Mátíù 27:22-26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Pílátù sọ fún wọn pé: “Kí wá ni kí n ṣe sí Jésù tí wọ́n ń pè ní Kristi?” Gbogbo wọ́n sọ pé: “Kàn án mọ́gi!”*+ 23 Ó sọ pé: “Kí ló dé? Nǹkan burúkú wo ló ṣe?” Síbẹ̀, wọ́n túbọ̀ ń kígbe ṣáá pé: “Kàn án mọ́gi!”+
24 Nígbà tó rí i pé òun ò rí nǹkan kan ṣe sí i, àmọ́ tí ariwo ń sọ, Pílátù bu omi, ó sì wẹ ọwọ́ rẹ̀ níwájú àwọn èrò náà, ó sọ pé: “Ọwọ́ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí. Ẹ̀yin fúnra yín ni kí ẹ lọ wá nǹkan ṣe sí i.” 25 Ni gbogbo àwọn èèyàn náà bá dá a lóhùn pé: “Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sórí àwa àti àwọn ọmọ wa.”+ 26 Ó wá tú Bárábà sílẹ̀ fún wọn, àmọ́ ó ní kí wọ́n na Jésù,+ ó sì fà á lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kàn án mọ́gi.+
-
-
Máàkù 15:12-15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Pílátù tún fún wọn lésì pé: “Kí wá ni kí n ṣe sí ẹni tí ẹ̀ ń pè ní Ọba Àwọn Júù?”+ 13 Wọ́n ké jáde lẹ́ẹ̀kan sí i pé: “Kàn án mọ́gi!”*+ 14 Àmọ́ Pílátù sọ fún wọn pé: “Kí ló dé? Nǹkan burúkú wo ló ṣe?” Síbẹ̀, wọ́n túbọ̀ kígbe pé: “Kàn án mọ́gi!”+ 15 Torí náà, kí Pílátù lè tẹ́ àwọn èrò náà lọ́rùn, ó tú Bárábà sílẹ̀ fún wọn; lẹ́yìn tó sì ní kí wọ́n na Jésù,+ ó fà á lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kàn án mọ́gi.+
-