ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Mátíù 14:19-21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Ó wá sọ fún àwọn èrò náà pé kí wọ́n jókòó* sórí koríko. Lẹ́yìn náà, ó mú búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó wo ojú ọ̀run, ó sì súre,+ lẹ́yìn tó bu búrẹ́dì náà, ó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì fún àwọn èrò náà. 20 Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó, wọ́n sì kó èyí tó ṣẹ́ kù jọ, ó kún apẹ̀rẹ̀ méjìlá (12).+ 21 Àwọn tó jẹun tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.+

  • Máàkù 6:39-44
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 39 Ó wá sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n jókòó* sórí koríko tútù ní àwùjọ-àwùjọ.+ 40 Torí náà, wọ́n jókòó* ní àwùjọ ọgọ́rọ̀ọ̀rún àti àràádọ́ta. 41 Ó wá mú búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó wo ojú ọ̀run, ó sì súre.+ Lẹ́yìn náà, ó bu àwọn búrẹ́dì náà sí wẹ́wẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé kí wọ́n gbé e síwájú àwọn èèyàn náà, ó sì pín ẹja méjì náà fún gbogbo wọn. 42 Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó, 43 wọ́n sì kó èyí tó ṣẹ́ kù jọ, ó kún apẹ̀rẹ̀ méjìlá (12), yàtọ̀ sí àwọn ẹja náà.+ 44 Àwọn tó jẹ búrẹ́dì náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin.

  • Lúùkù 9:14-17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Ní tòótọ́, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin ni wọ́n. Àmọ́ ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ní kí wọ́n jókòó ní àwùjọ-àwùjọ, kí àwùjọ kọ̀ọ̀kan jẹ́ nǹkan bí àádọ́ta (50) èèyàn.” 15 Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì ní kí gbogbo wọn jókòó. 16 Lẹ́yìn náà, ó mú búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó wo ojú ọ̀run, ó sì súre sórí wọn. Ó wá bù ú sí wẹ́wẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé kí wọ́n gbé e síwájú àwọn èrò náà. 17 Torí náà, gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó, wọ́n sì kó èyí tó ṣẹ́ kù jọ, ó kún apẹ̀rẹ̀ méjìlá (12).+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́