38 Àmọ́ tí mo bá ń ṣe é, bí ẹ ò tiẹ̀ gbà mí gbọ́, ẹ gba àwọn iṣẹ́ náà gbọ́,+ kí ẹ lè wá mọ̀, kí ẹ sì túbọ̀ máa mọ̀ pé Baba wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, mo sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Baba.”+
11 “Mi ò sí ní ayé mọ́, àmọ́ àwọn wà ní ayé,+ mo sì ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ. Baba mímọ́, máa ṣọ́ wọn+ nítorí orúkọ rẹ, tí o ti fún mi, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan* bí àwa ṣe jẹ́ ọ̀kan.*+
21 kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan,+ bí ìwọ Baba ṣe wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, tí mo sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ,+ kí àwọn náà lè wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wa, kí ayé lè gbà gbọ́ pé ìwọ lo rán mi.