ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jòhánù 14:30
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 30 Mi ò ní bá yín sọ̀rọ̀ púpọ̀ mọ́, torí alákòóso ayé+ ń bọ̀, kò sì ní agbára kankan lórí mi.*+

  • Jòhánù 16:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 lẹ́yìn náà, nípa ìdájọ́, torí pé a ti dá alákòóso ayé yìí lẹ́jọ́.+

  • Ìṣe 26:17, 18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Màá sì gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn yìí àti lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí màá rán ọ sí+ 18 láti la ojú wọn,+ láti mú wọn kúrò nínú òkùnkùn+ wá sínú ìmọ́lẹ̀+ àti láti mú wọn kúrò lábẹ́ àṣẹ Sátánì+ wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà,+ kí wọ́n sì rí ogún láàárín àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn nínú mi ti sọ wọ́n di mímọ́.’

  • 2 Kọ́ríńtì 4:3, 4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Tí ìhìn rere tí à ń kéde bá wà lábẹ́ ìbòjú lóòótọ́, á jẹ́ pé ó wà lábẹ́ ìbòjú láàárín àwọn tó ń ṣègbé, 4 láàárín àwọn tí ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí*+ ti fọ́ ojú inú àwọn aláìgbàgbọ́,+ kí ìmọ́lẹ̀* ìhìn rere ológo nípa Kristi, ẹni tó jẹ́ àwòrán Ọlọ́run,+ má bàa mọ́lẹ̀ wọlé.+

  • Éfésù 2:1, 2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 Síwájú sí i, Ọlọ́run sọ yín di ààyè, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti kú nínú àṣemáṣe àti ẹ̀ṣẹ̀ yín,+ 2 nínú èyí tí ẹ ti rìn nígbà kan rí lọ́nà ti ètò àwọn nǹkan* ayé yìí,+ lọ́nà ti ẹni tó ń darí àṣẹ afẹ́fẹ́,+ ẹ̀mí+ tó ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ aláìgbọràn.

  • 1 Jòhánù 5:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 A mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run la ti wá, àmọ́ gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́