2 Ló bá sáré wá bá Símónì Pétérù àti ọmọ ẹ̀yìn kejì, ẹni tí Jésù nífẹ̀ẹ́ gan-an,+ ó sì sọ fún wọn pé: “Wọ́n ti gbé Olúwa kúrò nínú ibojì,+ a ò sì mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.”
7 Ni ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù nífẹ̀ẹ́+ bá sọ fún Pétérù pé: “Olúwa ni!” Bí Símónì Pétérù ṣe gbọ́ pé Olúwa ni, ó wọ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,* torí pé ìhòòhò ló wà,* ó sì bẹ́ sínú òkun.