23Torí náà, èrò rẹpẹtẹ náà gbéra, gbogbo wọn pátá, wọ́n sì mú un lọ sọ́dọ̀ Pílátù.+2 Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ̀sùn kàn án+ pé: “A rí i pé ọkùnrin yìí fẹ́ dojú ìjọba ilẹ̀ wa dé, ó ní ká má ṣe san owó orí fún Késárì,+ ó sì ń pe ara rẹ̀ ní Kristi ọba.”+
12 Torí èyí, Pílátù ṣáà ń wá bó ṣe máa tú u sílẹ̀, àmọ́ àwọn Júù kígbe pé: “Tí o bá tú ọkùnrin yìí sílẹ̀, o kì í ṣe ọ̀rẹ́ Késárì. Ṣe ni gbogbo ẹni tó bá pe ara rẹ̀ ní ọba ń ta ko* Késárì.”+