-
1 Pétérù 5:2-4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run+ tó wà níkàáwọ́ yín, kí ẹ máa ṣe alábòójútó,* kì í ṣe tipátipá àmọ́ kó jẹ́ tinútinú níwájú Ọlọ́run; + kó má ṣe jẹ́ nítorí èrè tí kò tọ́,+ àmọ́ kí ẹ máa fi ìtara ṣe é látọkàn wá; 3 ẹ má ṣe jẹ ọ̀gá lórí àwọn tó jẹ́ ogún Ọlọ́run,+ àmọ́ kí ẹ jẹ́ àpẹẹrẹ fún agbo.+ 4 Tí a bá sì fi olórí olùṣọ́ àgùntàn+ hàn kedere, ẹ máa gba adé ògo tí kì í ṣá.+
-