16 Ó tún sọ fún un lẹ́ẹ̀kejì pé: “Símónì ọmọ Jòhánù, ṣé o nífẹ̀ẹ́ mi?” Ó dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, o mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ọ.” Ó sọ fún un pé: “Máa bójú tó àwọn àgùntàn mi kéékèèké.”+
28 Ẹ kíyè sí ara yín+ àti gbogbo agbo, láàárín èyí tí ẹ̀mí mímọ́ ti yàn yín ṣe alábòójútó,+ láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run,+ èyí tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ òun fúnra rẹ̀ rà.+