5Nítorí a mọ̀ pé tí ilé wa ní ayé bá wó,*+ ìyẹn àgọ́ yìí, Ọlọ́run máa fún wa ní ilé míì, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́,+ tó jẹ́ ti ayérayé ní ọ̀run. 2 Nítorí à ń kérora nínú ilé* yìí lóòótọ́, ó sì ń wù wá gan-an pé ká gbé èyí tó wà fún wa* láti ọ̀run* wọ̀,+