-
Ìṣe 15:7-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ atótónu,* Pétérù dìde, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, ẹ mọ̀ dáadáa pé tipẹ́tipẹ́ ni Ọlọ́run ti yàn mí láàárín yín pé kí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere látẹnu mi, kí wọ́n sì gbà gbọ́.+ 8 Ọlọ́run tí ó mọ ọkàn+ sì jẹ́rìí sí i ní ti pé ó fún wọn ní ẹ̀mí mímọ́,+ bó ṣe fún àwa náà. 9 Kò sì fi ìyàtọ̀ kankan sáàárín àwa àti àwọn,+ àmọ́ ó wẹ ọkàn wọn mọ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́.+
-