34 Ni Pétérù bá bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀, ó ní: “Ní báyìí, ó ti wá yé mi dáadáa pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú,+35 àmọ́ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tó bá bẹ̀rù rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ ni ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.+
16 Ni mo bá rántí ọ̀rọ̀ tí Olúwa máa ń sọ, pé: ‘Jòhánù fi omi batisí,+ àmọ́ a ó fi ẹ̀mí mímọ́ batisí yín.’+17 Torí náà, tí Ọlọ́run bá fún wọn ní ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kan náà tí ó fún àwa tí a ti gba Jésù Kristi Olúwa gbọ́, ta ni èmi tí màá fi dí Ọlọ́run lọ́wọ́?”*+