10 kí gbogbo yín àti gbogbo èèyàn Ísírẹ́lì yáa mọ̀ pé ní orúkọ Jésù Kristi ará Násárẹ́tì,+ ẹni tí ẹ kàn mọ́gi,*+ àmọ́ tí Ọlọ́run gbé dìde kúrò nínú ikú,+ ni ọkùnrin yìí fi dúró níbí pẹ̀lú ara yíyá gágá níwájú yín.
30 Àmọ́ Ọlọ́run gbé e dìde kúrò nínú ikú,+31 ọjọ́ púpọ̀ ni àwọn tó bá a lọ láti Gálílì sí Jerúsálẹ́mù fi rí i. Àwọn yìí ló wá ń jẹ́rìí nípa rẹ̀ fún àwọn èèyàn.+