-
2 Kọ́ríńtì 11:23-27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Ṣé òjíṣẹ́ Kristi ni wọ́n? Mo fèsì bí ayírí, mo jẹ́ òjíṣẹ́ Kristi lọ́nà tó ta wọ́n yọ: mo ti ṣiṣẹ́ jù wọ́n lọ,+ wọ́n ti jù mí sẹ́wọ̀n lọ́pọ̀ ìgbà,+ wọ́n ti lù mí láìmọye ìgbà, ọ̀pọ̀ ìgbà sì ni ẹ̀mí mi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́.+ 24 Ìgbà márùn-ún ni àwọn Júù nà mí ní ẹgba mọ́kàndínlógójì (39),+ 25 ìgbà mẹ́ta ni wọ́n ti fi ọ̀pá nà mí,+ wọ́n sọ mí lókùúta lẹ́ẹ̀kan,+ ìgbà mẹ́ta ni mo ti wọkọ̀ tó rì,+ mo sì ti lo ọ̀sán kan àti òru kan lórí agbami òkun; 26 nínú ìrìn àjò lọ́pọ̀ ìgbà, nínú ewu odò, nínú ewu dánàdánà, nínú ewu látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tèmi,+ nínú ewu látọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,+ nínú ewu láàárín ìlú,+ nínú ewu láàárín aginjù, nínú ewu lójú òkun, nínú ewu láàárín àwọn èké arákùnrin, 27 nínú òpò* àti làálàá, nínú àìlèsùn lóru lọ́pọ̀ ìgbà,+ nínú ebi àti òùngbẹ,+ nínú àìsí oúnjẹ lọ́pọ̀ ìgbà,+ nínú òtútù àti àìrí aṣọ wọ̀.*
-