5 Ní báyìí, kí Ọlọ́run tó ń fúnni ní ìfaradà àti ìtùnú jẹ́ kí ẹ ní èrò kan náà pẹ̀lú Kristi Jésù láàárín ara yín, 6 kí ẹ lè jọ+ máa fi ohùn* kan yin Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi lógo.
10 Ní báyìí, mo fi orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi rọ̀ yín, ẹ̀yin ará, pé kí gbogbo yín máa fohùn ṣọ̀kan àti pé kí ìyapa má ṣe sí láàárín yín,+ àmọ́ kí ẹ ní inú kan náà àti èrò kan náà.+
11 Tóò, ẹ̀yin ará, ẹ máa yọ̀, ẹ máa ṣe ìyípadà, ẹ máa gba ìtùnú,+ ẹ máa ronú níṣọ̀kan,+ ẹ máa gbé ní àlàáfíà;+ Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà+ yóò sì wà pẹ̀lú yín.