-
1 Tímótì 3:2-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Nítorí náà, alábòójútó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí kò lẹ́gàn, tí kò ní ju ìyàwó kan lọ, tí kì í ṣe àṣejù, tó ní àròjinlẹ̀,*+ tó wà létòlétò, tó ń ṣe aájò àlejò,+ tó kúnjú ìwọ̀n láti kọ́ni,+ 3 kì í ṣe ọ̀mùtí,+ kì í ṣe oníwà ipá,* àmọ́ kó máa fòye báni lò,+ kì í ṣe oníjà,+ kì í ṣe ẹni tó fẹ́ràn owó,+ 4 kó jẹ́ ọkùnrin tó ń bójú tó* ilé rẹ̀ dáadáa, tí àwọn ọmọ rẹ̀ máa ń tẹrí ba, tí wọ́n sì jẹ́ onígbọràn+ 5 (torí tí ọkùnrin kan ò bá mọ bó ṣe máa bójú tó* ilé ara rẹ̀, báwo ló ṣe máa bójú tó ìjọ Ọlọ́run?), 6 kì í ṣe ẹni tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yí lọ́kàn pa dà,+ torí ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga, kó sì ṣubú sínú ìdájọ́ tí a ṣe fún Èṣù. 7 Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ kí àwọn tó wà níta+ máa sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa* kó má bàa ṣubú sínú ẹ̀gàn* àti pańpẹ́ Èṣù.
-